Monday, December 12, 2022

Iwe GẸNẸSISI Ori Kejilelogoji Yoruba Version - Bibeli Mimo Ti GFM


Kaa ni Ede Oyinbo (Read it in English Version)


 GẸNẸSISI, Ori Kejilelogoji 


GẸNẸSISI 



Àwọn arákùnrin Josẹfu lọ sí Ejibiti
1Nígbà tí Jakọbu mọ̀ pé ọkà wà ní Ejibiti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pé, “Èéṣe tí ẹ ń wo ara yín lásán?” 2 “Mo tí gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Ejibiti. Ẹ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibẹ̀ kí ẹ sì rà wá fún wa, kí a má ba à kú.”
3Nígbà náà ni mẹ́wàá nínú àwọn arákùnrin Josẹfu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti ra ọkà. 4Ṣùgbọ́n Jakọbu kò rán Benjamini àbúrò Josẹfu lọ pẹ̀lú wọn nítorí ẹ̀rù ń bà á kí aburú má ba à ṣẹlẹ̀ sí i. 5 Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli wà lára àwọn tó lọ Ejibiti lọ ra oúnjẹ nítorí ìyàn náà mú ni ilẹ̀ Kenaani pẹ̀lú.
6Nísinsin yìí, Josẹfu ni alábojútó fún gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, òun sì ni ó ń bojútó ọkà títà fún gbogbo ènìyàn ìlú náà. Nítorí náà nígbà tí àwọn arákùnrin Josẹfu dé, wọ́n tẹríba, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Josẹfu. 7Lọ́gán tí Josẹfu ti rí àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó ti dá wọn mọ̀, ṣùgbọ́n ó ṣe bí i wí pé kò mọ̀ wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ líle sí wọn. Ó béèrè pé, “Níbo ni ẹ ti wá?”
Wọ́n sì dáhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kenaani ni a ti wá ra oúnjẹ.”
8Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Josẹfu mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, síbẹ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ kò mọ̀ ọ́n. 9 Nígbà náà ni ó rántí àlá rẹ̀ tí ó lá sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ayọ́lẹ̀wò (Amí) ni yín, ẹ wá láti wo àṣírí ilẹ̀ wa ni.”
10Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ olúwa wa, àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá láti ra oúnjẹ ni, 11Ọmọ baba ni wá, olóòtítọ́ ènìyàn sì ni wá pẹ̀lú, àwa kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò.”
12Ó wí fún wọn pé, “Rárá! Ẹ wá láti wo àṣírí ilẹ̀ wa ni.”
13Ṣùgbọ́n wọ́n tún dáhùn pé, “Arákùnrin méjìlá ni àwa ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ baba kan náà, tí ó ń gbé ní ilẹ̀ Kenaani. Èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa ń bẹ lọ́dọ̀ baba wa, ọ̀kan sì ti kú.”
14Josẹfu wí fún wọn pé, “Bí mo ti wí fún un yín náà ni: Ayọ́lẹ̀wò ni yín! 15Èyí sì ni a ó fi dán an yín wò, èmi búra pé, níwọ̀n ìgbà tí Farao bá wà láààyè, ẹ kì yóò kúrò níbí, àyàfi bí arákùnrin yín kan tókù bá wá sí ibí. 16Ẹ rán ọ̀kan nínú yín lọ láti mú arákùnrin yín wá, àwa yóò fi ẹ̀yin tókù pamọ́ sínú túbú, kí àwa ba à lè mọ bóyá òtítọ́ ni ẹ̀yin ń wí. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé irọ́ ni ẹ̀yin ń pa, ní òtítọ́ bí Farao ti ń bẹ láààyè ayọ́lẹ̀wò ni yín!” 17Ó sì fi gbogbo wọn sínú túbú fún ọjọ́ mẹ́ta.
18Ní ọjọ́ kẹta, Josẹfu wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe kí ẹ̀yin ba à le yè nítorí mo bẹ̀rù Ọlọ́run: 19Tí ó bá jẹ́ pé olóòtítọ́ ènìyàn ni yín, ẹ jẹ́ kí ọ̀kan nínú yín dúró ni túbú ní ìhín, nígbà tí àwọn yòókù yín yóò gbé ọkà lọ fún àwọn ará ilé e yín tí ebi ń pa. 20Ṣùgbọ́n ẹ gbọdọ̀ mú arákùnrin tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn yín wá, kí n ba à le mọ òtítọ́ ohun ti ẹ ń wí, kí ẹ má ba à kú.” Wọn sì gbà láti ṣe èyí.
21Wọ́n ń sọ ọ́ láàrín ara wọn wí pé, “Àwa jẹ̀bi nítòótọ́ nípa ti arákùnrin wa. A rí ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá nítorí ẹ̀mí rẹ̀, ṣùgbọ́n a kò gbẹ́bẹ̀, nítorí náà ni ìdààmú yìí fi dé bá wa.”
21Wọ́n ń sọ ọ́ láàrín ara wọn wí pé, “Àwa jẹ̀bi nítòótọ́ nípa ti arákùnrin wa. A rí ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá nítorí ẹ̀mí rẹ̀, ṣùgbọ́n a kò gbẹ́bẹ̀, nítorí náà ni ìdààmú yìí fi dé bá wa.”
22 Reubeni dá wọn ní ohùn pé, “Èmi kò wí fún yín pé kí ẹ má se ṣẹ̀ sí ọmọdékùnrin náà? Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́! ṣùgbọ́n nísinsin yìí a ń béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ wa.” 23Wọn kò sì mọ̀ pé, Josẹfu ń gbọ́ wọn ní àgbọ́yé nítorí ògbufọ̀ ni ó ń lò tẹ́lẹ̀.
24Ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún. Ó sì tún yí padà sí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀. Ó mú Simeoni kúrò láàrín wọn, ó sì dè é ní ojú wọn.
25Josẹfu pàṣẹ pé kí wọn bu ọkà kún inú àpò wọn, kí wọn sì mú owó ẹnìkọ̀ọ̀kan padà sínú àpò rẹ̀, kí wọn sì fún wọn ní ohun tí wọn yóò lò nírín-àjò wọn padà sílé. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe èyí fún wọn, 26Wọn gbé ẹrù wọn lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọn sì padà lọ sí ilé.
27Níbi tí wọ́n ti dúró láti sùn lóru ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú wọn tú àpò rẹ̀ láti mú oúnjẹ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì rí owó rẹ̀ ní ẹnu àpò rẹ̀. 28Ó sì wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “a ti dá owó mi padà, òun nìyí ní ẹnu àpò mi.”
Ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Èwo nìyí tí Ọlọ́run ṣe sí wa yìí.”
29Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un wí pé, 30“Ọkùnrin náà tí í ṣe alábojútó ilẹ̀ náà, sọ̀rọ̀ líle sí wa, ó sì fi ẹ̀sùn kàn wá pé a wá yọ́ ilẹ̀ náà wò ni. 31Ṣùgbọ́n, a wí fún un pé, ‘Rárá o, olóòtítọ́ ènìyàn ni wá, a kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò. 32Arákùnrin méjìlá ni wá, ọmọ baba kan náà, ọ̀kan ti kú, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wà lọ́dọ̀ baba wa ni ilẹ̀ Kenaani.’
33“Nígbà náà ni ọkùnrin tí ó jẹ́ alábojútó ilẹ̀ náà wí fún wa pé, ‘Báyìí ni n ó ṣe mọ̀ bóyá olóòtítọ́ ènìyàn ni yín; Ẹ fi ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ níbí, pẹ̀lú mi, ẹ sì mú oúnjẹ lọ fún àwọn ará ilé yín tí ebi ń pa kú lọ, lọ́wọ́ ìyàn. 34Ṣùgbọ́n ẹ mú arákùnrin yín tí ó kéré jùlọ wá fún mi kí n le mọ̀ pé dájúdájú ẹ kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò bí kò ṣe ènìyàn tòótọ́. Nígbà náà ni n ó mú arákùnrin yín padà fún un yín, lẹ́yìn náà ẹ le máa wá ṣe òwò bí ó ti wù yín ní ilẹ̀ yìí.’ ”
35Bí wọ́n sì ti ń tú àpò ẹrù wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan bá owó tí ó san fún ọjà náà lẹ́nu àpò rẹ̀! Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi, àwọn àti baba wọn. 36Jakọbu baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ ti mú mi pàdánù àwọn ọmọ mi. N kò rí Josẹfu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì rí Simeoni náà mọ. Ẹ sì tún fẹ́ mú Benjamini lọ! Èmi ni gbogbo ohun búburú yìí wá ń ṣẹlẹ̀ sí.”
37Nígbà náà ni Reubeni wí fún baba rẹ̀ pé, “Pa àwọn ọmọ mi méjèèjì bí n kò bá mú Benjamini padà wá fún ọ, èmi ni kí o fà á lé lọ́wọ́, n ó sì mu un padà wá.”
38Ṣùgbọ́n Jakọbu wí pé, “Ọmọ mi kì yóò bá a yín lọ, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀. Bí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ sí i, ìbànújẹ́ ni yóò sì pa mi kú ni ọjọ́ ogbó mi yìí."


Ka eyi t'oku iweGenesis1 | 2 | 3 | 4 | 5 | 6 | 7 | 8 | 9 | 10 | 11 | 12 | 13 | 14 | 15 | 16 | 17 | 18 | 19 | 20 | 21 | 22 | 23 | 24 | 25 | 26 | 27 | 28 | 29 | 30 | 31 | 32 | 33 | 34 | 35 | 36 | 37 | 38 | 39 | 40 | 41 | 42 | 43 | 44 | 45 | 46 | 47 | 48 | 49 | 50


To join GFM Drama Group/YFE Film & Theater Production, Call: +2348147499400, DM WhatsApp: +2347036517985 


You are in Need of Composed Gospel Songs to the Studio, call: +2348147499400, DM Whatsaap: +2347036517985 


See Live Drama Stage Pictures of PastorPrinceAOAdeyinka (aka Pastor Ronusi OBA) at Agent of Light Drama Night RCCG Province 4


GFM Bible - New Testament:   Mathew | Mark |Luke | John | Acts | Romans | I Corinthians | II Corinthians | Galathians | Ephesians | Philippians | Colossians | I Tesalonians | II Tesalonians | I Timothy | II Timothy | Titus | Philemon | Hebrews | James | I Peter | II Peter | I John | II John | III John | Jude | Revelation 


GFM Bible - Old Testament:  Genesis | Exodus | Letivicus | Number | Deuteronomy | Joshua | Judges | Ruth | I Samuel | II Samuel | I Kings | II Kings | I Chronicles | II Chronicles | Ezra | Nehemiah | Esther | Job | Psalms | Proverbs | Ecclesiastes | Song of Solomon | Isaiah | Jeremiah | Lamentations | Ezekiel |  Daniel | Hosea | Joel | Amos | Obadiah | Jonah | Micah | Nahum | Habakkuk | Zephaniah | Haggai | Zechariah | Malachi

Always check for more updates. . .


WHAT DO YOU THINK? - We have all sinned and deserve God's judgment. God, the Father, sent His only Son to satisfy that judgment for those who believe in Him. Jesus, the creator and eternal Son of God, who lived a sinless life, loves us so much that He died for our sins, taking the punishment that we deserve, was buried, and rose from the dead according to the Bible. If you truly believe and trust this in your heart, receiving Jesus alone as your Savior, declaring, "Jesus is Lord," you will be saved from judgement, and spend eternity with God in heaven.

What is your response?
Yes, today, I'm deciding to follow Jesus

Yes, I'm already the follower of Jesus.


If you would like to DONATE to Ykamazingworld Freelance Enterprise, please CLICK HERE

To meet your needs with YFE click on: http://metyourneeds.blogspot.com/

More About YFE:  

Goto our Sections Business sites: 

          One hold, Once united,  One world... 

              Together, we rise to the future.

Sunday, December 11, 2022

Genesis Chapter 42 English Version - GFM Holy Bible

Read it in Yoruba Version

Genesis Chapter 42


Genesis


Joseph Meets His Brothers

42 Now Jacob saw that there was grain in Egypt, so Jacob said to his sons, “Why are you looking at each other?” Then he said, “Look! I’ve heard that there’s grain in Egypt. Go down there and buy some grain for us there so that we’ll live and not die.”

So Joseph’s brothers went down, ten of them, to buy grain from Egypt. But Benjamin, Joseph’s brother, Jacob did not send, for he said, “An accident might happen to him.”

The sons of Israel went to buy grain among the others who were coming, because the famine was in the land of Canaan. Now Joseph was the ruler over the land. He was the provider of grain for all the people of the earth. Then Joseph’s brothers came and bowed down to him with faces to the ground. When Joseph saw his brothers, he recognized them, but he made himself unrecognizable to them. Then he spoke harshly and said to them, “Where have you come from?”

“From the land of Canaan,” they said, “to buy grain as food.”

Though Joseph recognized his brothers, they did not recognize him. Then Joseph remembered the dreams he had dreamed about them. He said to them, “You’re spies! You’ve come to see the undefended places in the land.”

10 “No, my lord!” they said to him. “Your servants came to buy grain as food. 11 All of us—we are sons of one man. We’re honest. Your servants have never been spies.”

12 “Not so,” he said to them. “Rather, you’ve come to see the undefended places in the land.”

13 But they said, “We your servants are twelve brothers, sons of one man in the land of Canaan. Look, the youngest is with our father today and the other one is no more.”

14 Joseph said to them, “It’s just like I told you when I said, ‘You’re spies.’ 15 By this you’ll be tested: by the life of Pharaoh, you’ll not leave from here until your youngest brother comes here! 16 Send one from among yourselves to get your brother, while you remain confined, in order to test your words, to see whether the truth is with you. If not, by the life of Pharaoh, you’re definitely spies!”

17 So he put them together in custody for three days. 18 Then Joseph said to them on the third day, “Do this and you will live. I fear God. 19 If you’re honest, let one of your brothers remain as a prisoner in the guardhouse where you’ve been, while you, go and bring grain for the hunger in your homes. 20 And your youngest brother, bring to me so that your words can be verified—and you won’t die.” So they did.

21 Then each man said to his brother, “We’re truly guilty for our brother. We saw the distress of his soul when he begged us for mercy, but we didn’t listen. That’s why this distress has come to us.”

22 Reuben answered them and said, “Didn’t I tell you, ‘Don’t sin against the boy’? But you didn’t listen. Now, see how his blood is now being accounted for.”

23 They did not know that Joseph was listening, since there was an interpreter between them. 24 He turned away from them and wept. When he turned back to them and spoke to them, he took Simeon from them and tied him up before their eyes.

25 Then Joseph gave orders to fill their bags with grain, to return each man’s money to his sack, and to give them provisions for the journey. So it was done for them. 26 Then they loaded their grain on their donkeys and left from there. 27 As one of them opened his sack to give fodder to his donkey at the lodge, he saw his money—behold, it was in the opening of his bag. 28 So he said to his brothers, “My money has been returned! Look, it’s in my bag.”

Their hearts sank. Trembling, each one turned to his brother and said, “What is this that God has done to us?”

29 When they came to their father Jacob, in the land of Canaan, they told him all that had happened to them, saying, 30 “The man, the lord of the land, spoke with us harshly, and took us as spies of the land. 31 But we said to him, ‘We’re honest. We’ve never been spies. 32 We are twelve brothers, sons of our father. One is no more and the youngest is with our father today in the land of Canaan.’ 33 Then the man, the lord of the land, said to us, ‘By this I’ll know if you’re honest: leave one of your brothers with me. As for the hunger of your homes: take and go! 34 Then bring your youngest brother to me, so that I may know you are not spies, but you are honest. I’ll give you back your brother and you can move about freely in the land.’”

35 Now as they were emptying their sacks, behold, there was each man’s bundle of money in his sack. When they saw their money bundles, they and their father, they were afraid.

36 Then their father Jacob said to them, “You’ve made me childless! Joseph is no more. Now Simeon is gone, and next you’ll take Benjamin! Everything is against me!”

37 Then Reuben spoke to his father, saying, “You can put my two sons to death if I don’t bring him back to you. Put him in my hand and I—I will return him to you.”

38 But he said, “My son will not go down with you—for his brother is dead and he alone remains. And if harm should happen to him along the way you’re going, you’ll bring my grey hair down to Sheol in grief.”


Read it in Yoruba Version


Read the rest of, Genesis1 | 2 | 3 | 4 | 5 | 6 | 7 | 8 | 9 | 10 | 11 | 12 | 13 | 14 | 15 | 16 | 17 | 18 | 19 | 20 | 21 | 22 | 23 | 24 | 25 | 26 | 27 | 28 | 29 | 30 | 31 | 32 | 33 | 34 | 35 | 36 | 37 | 38 | 39 | 40 | 41 | 42 | 43 | 44 | 45 | 46 | 47 | 48 | 49 | 50


To join GFM Drama Group/YFE Film & Theater Production, Call: +2348147499400, DM WhatsApp: +2347036517985 


You are in Need of Composed Gospel Songs to the Studio, call: +2348147499400, DM Whatsaap: +2347036517985 


See Live Drama Stage Pictures of PastorPrinceAOAdeyinka (aka Pastor Ronusi OBA) at Agent of Light Drama Night RCCG Province 4


GFM Bible - New Testament:   Mathew | Mark |Luke | John | Acts | Romans | I Corinthians | II Corinthians | Galathians | Ephesians | Philippians | Colossians | I Tesalonians | II Tesalonians | I Timothy | II Timothy | Titus | Philemon | Hebrews | James | I Peter | II Peter | I John | II John | III John | Jude | Revelation 


GFM Bible - Old Testament:  Genesis | Exodus | Letivicus | Number | Deuteronomy | Joshua | Judges | Ruth | I Samuel | II Samuel | I Kings | II Kings | I Chronicles | II Chronicles | Ezra | Nehemiah | Esther | Job | Psalms | Proverbs | Ecclesiastes | Song of Solomon | Isaiah | Jeremiah | Lamentations | Ezekiel |  Daniel | Hosea | Joel | Amos | Obadiah | Jonah | Micah | Nahum | Habakkuk | Zephaniah | Haggai | Zechariah | Malachi

Always check for more updates. . .


WHAT DO YOU THINK? - We have all sinned and deserve God's judgment. God, the Father, sent His only Son to satisfy that judgment for those who believe in Him. Jesus, the creator and eternal Son of God, who lived a sinless life, loves us so much that He died for our sins, taking the punishment that we deserve, was buried, and rose from the dead according to the Bible. If you truly believe and trust this in your heart, receiving Jesus alone as your Savior, declaring, "Jesus is Lord," you will be saved from judgement, and spend eternity with God in heaven.

What is your response?
Yes, today, I'm deciding to follow Jesus

Yes, I'm already the follower of Jesus.


If you would like to DONATE to Ykamazingworld Freelance Enterprise, please CLICK HERE

To meet your needs with YFE click on: http://metyourneeds.blogspot.com/

More About YFE:  

Goto our Sections Business sites: 

          One hold, Once united,  One world... 

              Together, we rise to the future.